OBÌNRIN KAN LẸ́Ẹ̀KAN ṢOṢO "Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÀWỌN OBÌNRIN NÍ Cyprus NI KÒ MỌ Ẹ̀TỌ́ TÍ WỌ́N NÍ!"
ÌRAN ARA ẸNI LỌ́WÓ
O lè ran ara rẹ lọ́wọ́.
KÒ SÍ ÒFIN KANKAN NÍ CYPRUS TÓ NÍ KÍ ÈNÌYÀN MÁ DÚRÓ FÚN ARA RẸ̀ NÍLÉ ẸJỌ́ TÀBÍ TÓ NÍ KÍ ENIYAN MÁ ṢE OHUN FÚNRA RẸ̀ NÍLÉ ẸJỌ́.
OWAAT máa ń tọ́ àwọn obìnrin tí a ti lò nílòkulò sọ́nà láti ró wọn lágbára. A ó sì fi òfin sí ọwọ́ wọn àti,
- láti mọ ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn;
- láti lè gba ẹjọ́ ara wọn rò
- láti lè ran ara Wọn lọ́wọ́ fúnra wọn;
- láti mú ẹjọ́ wá lórí ohun pàjáwìrì sílé ẹjọ́ fún ààbò wọn lórí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn, iyì ọmọ ènìyàn àti àyè ibi ìkọ̀kọ̀ wọn.
NJẸ́ O MỌ̀?
Ẹ̀tọ́ tí o ní láti lè dúró fún ara rẹ túmọ̀ sí pé o lè pe ẹjọ́ láti lè gba àṣẹ láti dènà ìlòkulò. Ààyè ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn rẹ sí ilé ẹjọ́ túmọ̀ sí pé o le ran ara rẹ lọ́wọ́, láti fi orúkọ sílẹ̀ láti lè lo ẹ̀tọ́ rẹ nílé ẹjọ́.
Kà á si…
ṢE É FÚNRA RẸ NINU IYÀRÁ ÌDÁJỌ́
Orílẹ̀-èdè Cyprus gbọ́dọ̀ ri dájú pé wọ́n fún àwọn obìnrin wọn lánfààní sí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn láti dojúkọ ìlòkulò gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ EU yòókù ṣe ṣe fún àwọn ọmọ ìlú wọn, tí wọn sì ń jẹ̀gbádùn ààbò lọ́wọ́ ìlòkulò ní ìlú wọn.
Kà á si…
GBA FỌỌMU
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin tí wọ́n ń dúró fún ara wọn nílé ẹjọ́ tí wọ́n jẹ́ Ọmọ-ẹgbẹ́ Àgbájọpọ̀ Ilẹ̀ Europe àti Ìgbìmọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè wọnyi ló ń gba ààbò láti fi òpin sí ìlòkulò wọn – fúnra wọn.
O lè ṣe é fúnra rẹ.
Kà á si…
NÍPA OWAAT
Kí ni ìtumọ̀ Obìnrin Kan Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo (OWAAT) - CYPRUS?
OWAAT túmọ̀ sí pé orílẹ̀-èdè Cyprus kò "fàyè sílẹ̀ rárá" fún Ìlòkulò Àwọn Obìnrin.
Ìlépa OWAAT ni láti máa ró gbogbo àwọn obìnrin tí a ti lò nílòkulò lágbára láti lè máa dènà ìwà ipá sí wọn láti lè pa wọ́n mọ́. Ìlépa OWAAT máa ń tọ́ àwọn obìnrin sọ́nà bí wọ́n ṣe lè fi òfin sí ọwọ́ ara wọn, kí wọ́n sì lè gba ẹjọ́ ara wọn rò. Àti kí wọ́n sì lè rí àyè sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú ààbò lọ́wọ́ ẹni tó hùwà burúkú sí wọn.
OWAAT ń rọ àwọn ilé-ẹjọ́ tó wà ní orílẹ̀-èdè Cyprus láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìlépa OWAAT nípa ṣíṣàmúlò "Fọ́ọ̀mù ìran ra ẹni lọ́wọ́" tó wà lórí wẹ́ẹ̀bù àti ìtọ́ni fún ẹni tó ń gba ẹjọ́ ara rẹ̀ rò, láti lè tẹ̀ ẹ́ síta, àti láti lè rí àyè sí fáìlì náà ní ilé-ẹjọ́ èyíkèyí ní orílẹ̀-èdè Cyprus pẹ̀lú ìdájọ́ tó yẹ láti lè rí àtúnṣe.
OWAAT máa ń pèsè àpẹẹrẹ àwọn ìtọ́kasí wẹ́ẹ̀bù, tó jẹ́ ètò ìbójútó ilé-ẹjọ́ tó wà lórí wẹ́ẹ̀bù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù àwọn ilé-ẹjọ́ ọmọ-ẹgbẹ́ EU àti gbogbo ilé-ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹrika ló ní fọ́ọ̀mù Ìran Ra Ẹni Lọ́wọ́, tí wọ́n sì ní ìtọ́kasí tó jọra wọn sí ilé-ẹjọ́ tí wọ́n ti pèsè ẹ̀sùn aabo ará ìlú àti ìtọ́ni láti ran àwọn tó gba ẹjọ́ ara wọn rò lọ́wọ́.
OWAAT ní Ilé ìwòsàn Kékeré fún ẹ̀sùn ní àwọn ìgbèríko. Abúlé Kokkinotrimithia ati Ile Awọn Arabinrin ti St. Josẹfu ni Old City, Nicosia ni OWAAT ṣí sí ní Oṣù Kẹwàá ní ọdún 2014. Ará ìlú fi ara wọn jì nípa ìpèsè àwọn ohun tí wọ́n máa nílò ní Gbọngan Ẹ̀sùn OWAAT ní ìgbèríko wọn. Àwọn aṣájú níbi òwò àti àwọn tókọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ máa ń fi àkókò wọn àti ọpọlọ iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Ìjọba ìlú àti àwọn tí wọ́n máa ń ṣòwò láìjèrè fi oríṣiríṣi ohun àti kọnputa tọrọ. Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn eniyan tí wọ́n fi ara wọn jì fún OWAAT ló mú gbọ̀ngán ẹ̀sùn fún àwọn obìnrin tí a ti lò nílòkúlò yìí dúró ní àdúgbò wọn, láti lè kọ́ wọn bí wọ́n yóò ṣe máa lo ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn ní ilé-ẹjọ́ pẹ̀lú ohùn wọn.
OWAAT jẹ́ Àjọṣepọ̀ Ilé-ẹjọ́ Àdúgbò tó ní Àtìlẹ́yín
"Oníkálùkù obìnrin ní orílẹ̀-èdè Cyprus ló lè sọ ara rẹ̀ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìlòkulò nítorí pé àwọn àyíká àti agbègbè àti ilé-ẹjọ́ wọn ni kò "fàyè gba" ìlòkulò rárá" - Patricia M. Martin, Esq., U.S. Fulbright Scholar – Cyprus, One Woman At A Time (OWAAT)
Ẹ̀BÙN
Tí gbogbo abúlé bá dìde, wọn yóò fi òpin sí ìlòkulò, Obìnrin Kan Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo.
Ẹ̀bùn yín ló ń jẹ́ kí OWAAT gbé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ṣe láti má fàyè gba Ìlòkulò sí Àwọn Obìnrin ní Cyprus:
- Ó fún àwọn obìnrin lánfààní láti lè máa pàdé ní ibi tó ní ààbò ní àdúgbò wọn láti jíròrò nípa ìlòkulò;
- A máa pèsè àyè fún àwọn obìnrin láti lè lọ sílé ẹjọ́ láti dúró fún ara wọn nípasẹ̀ fọ́ọ̀mù ìkọ́ni, èyí sì ń mú òpin dé bá ìlòkulò wọn;
- A máa ń pèsè ìtọ́ni ẹnìkan sí ẹnìkan fún àwọn obìnrin lórí bí wọ́n ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi òfin sí ọwọ́ ara wọn;
- A máa ń fún àwọn obìnrin ní ìtọ́sọ́nà ni ibi tí ààbò wà ní àdúgbò tí wọ́n ń gbè gangan;
- A máa ń tọ́ wọn sọ́nà bí wọn yóò ṣe fi ìròyìn ara wọn sílẹ̀ nínú fọ́ọ̀mù, àti bí wọn yóò ṣe gbé ẹjọ́ lọ sí ilé ẹjọ́ fún ìdáàbòbò ní àwọn ilé ẹjọ́ wọn;
- A máa ń mú àwọn obìnrin pàdé ara wọn, láti lè ran ara wọn lọ́wọ́, wọ́n yóò sì ní agbára papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti aláàdúgbò, ó sì lè jẹ́ mọ̀lẹ́bí mìíràn fún àwọn tí wọ́n bá nílò ààbò òfin láti lè dẹ̀nà ìlòkulò;
ONÍGBỌ̀WỌ́ & ALÁTÌLẸ́YÌN
FULBRIGHT
Obìnrin Kan Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo (OWAAT) - Cyprus, di ohun tó ṣeéṣe pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Fulbright láti orílẹ̀-èdè Amẹrika, 2014-2015.*
* Obìnrin Kan Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo (OWAAT) àti àwọn tó ṣẹ̀dá ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù yìí mọ̀ wì pè ètò yìí tí wọn ni, kì í ṣe ojú ìwé ẹnikẹ́ni tàbí ti Ilé ẹ̀kọ́ Gíga Nicosia àti wí pé gbogbo ìròyìn tó wà níbẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ ti wọn kò dúró fún ẹnikẹ́ni bí i Ètò Fulbright, CIES tàbí ti Ẹ̀ka Orílẹ̀-èdè Amẹrika tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Nicosia, Cyprus.
ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA TI NICOSIA
ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA TI NICOSIA, LÓ JẸ́ OLÙGBÀLEJÒ FÚN ÈTÒ OBÌNRIN KAN LẸ́Ẹ̀KAN ṢOṢO (OWAAT )NI CYPRUS, tí ẹ̀ka Ìmọ̀ Òfin Ilé ìwé Gíga náà sì ṣe agbátẹrù rẹ̀, Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Àrẹ àti Ilé Ẹjọ́ Tó Ga Jùlọ ní Cyprus àti Olórí Ilé Ẹjọ́ Ẹbí, ìyẹn Adájọ́ George Serghides. Kà á si...
PATRICIA M. MARTIN ATTORNEY AT LAW PC COLORADO • NEW MEXICO • DISTRICT OF COLUMBIA PO BOX 315 • DENVER, CO 80201 TẸL 1.866.226.1196 • FAKSI 1.866.226.3349 EMEELI pmmartinlaw@gmail.com
ALEXANDRA M. HADJIDAKI & ẸGBẸ́ TO KU
linkedin.com/in/alexhadjidaki
CTO & Project Manager for OWAAT Website & Branding Project - By Website & Branding team: Alexandra Hadjidaki, Ana Bujosevic and Daryna Dombik.
Ẹ̀RÍ
Àkójọpọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Àdúgbò OWAAT
Lóòní àwọn tó fi ara wọn jì láti ṣiṣẹ́ fún OWAAT, wọ́n fi àkókò wọn, ìmọ̀ọ́ṣe wọn, ìròyìn àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, ibi iṣẹ́ wọn àti ohun ìní wọn gbogbo tó kù sílẹ̀ fún àwọn obìnrin tí a ti lò nílòkulò, kí wọ́n bà á lè ní ibi tó ní ààbò. Kí wọ́n sì lè kọ́ wọn bí wọn ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́, láti lè lọ sí ilé ẹjọ́ fúnra wọn, kí wọ́n sì dúró lórí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn, kí wọ́n sì wá láti mú òpin bá ìlòkulò àṣẹ láti ilé ẹjọ́.
-
ADÁJỌ́ GEORGE A. SERGHIDES Ilé Ẹjọ́ Europe Fún Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn, Ni Strasbourg, France
“Mo rí OWAAT gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ṣe pàtàkì gan fún àwọn ìdí wọ̀nyí:
Ní àkọ́kọ́, ó jẹ́ ojúlówó èrò tó ń bójútó àwọn ènìyàn tí kò ní ìrànlọ́wọ́, àwọn ẹni tí a ti lò nílòkulò, tó ṣeéṣe kí wọ́n tòṣì, tí wọ́n sì nílò ìdájọ́ òdodo. OWAAT ń gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè lo ẹ̀tọ́ ọmọ eniyan àti òmìnira wọn.
Èkejì, ló lọ sí gbòngbò ìṣòro tó wà ní àwùjọ wa nítorí pé óń gbìyànjú ní gbogbo ọ̀nà tó rọrùn jùlọ láti fún wa ní gbogbo ìròyìn àti irinṣẹ́ òfin fún gbogbo àwọn tó nílò rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kò ní ọ̀nà mìíràn láti rí i. ”
Wo ni kikun testimonial… -
Ọ̀MỌ̀WÉ ANNA PLEVRI Olùkọ́, Ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Òfin Ìdílé, Ẹ̀ka Ìmọ̀ Nípa Ènìyàn Àti Òfin Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ti Nicosia / Agbẹjọ́ rò
“Àwọn obìnrin máa ń jìyà ipá nítorí pé wọ́n jẹ́ obìnrin. Ìwà ipá sí àwọn obìnrin ní gbogbo ọ̀nà ló fi jẹ́ ìtàpásí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. Nítorí ohun tí a sọ lókè yìí, OWAAT wá ń pèsè ànfààní àti àyè fún àwọn obìnrin láti kọ́ nípa ẹ̀tọ́ wọn, kí wọ́n sì dáàbòbò wọ́n, àti láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun yìí. OWAAT jẹ́ àjọ tó ń dásí ohun ní àwùjọ, wọ́n sì ń dá ààbò bo ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn.”
Wo ni kikun testimonial… -
ALEXANDRA HADJIDAKI Oníṣẹ́-Ọnà Wẹ́ẹ̀bù / CTO & Alábòójútó Ojú Ìwé Wẹ́ẹ̀bù OWAAT Àti Ìsàmì / Akẹ́kọ̀ọ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́nsì Fún Kọ̀npútà
“Mo pinnu láti jọ̀wọ́ ara mi gẹ́gẹ́ bí Alájọṣiṣẹ́pọ̀ Agbègbè nítorí pé mo gbàgbọ́ wí pé èyí lè jẹ́ àpẹẹrẹ ayò òun máa jẹ, yóò sì máa mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyípadà wá sí agbègbè náà. Ìgbàgbọ́ mi ni pé ìmọ̀ ẹ̀rọ lè so àwọn ènìyàn papọ̀ ní àwọn ọ̀nà tí kò seéṣe tẹ́lẹ̀ rí.”
Wo ni kikun testimonial… -
STELIOS ASPROFTAS STIKSIS MEDIATION SERVICES
“OWAAT ń ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Cyprus. Àpapọ̀ ìṣesí rere àwọn ènìyàn àti ọgbọ́n ìmọ̀ọ́ṣe gbogbo àwọn Alájọṣiṣẹpọ̀ OWAAT ló jẹ́ ohun pàtàkì fún àṣeyọrí wọn. “Kò sí Àyè Rárá” fún ìlòkulò àwọn obìnrin ní Cyprus yóò tẹ̀síwájú láti máa ní àṣeyọrí nípasẹ̀ ìlépa OWAAT.”
-
ALEXIS THEODOTOU Aláṣẹ Àgbà, ALEXIS THEODOTOU & CO. LLC
“Nígbà ti wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní àyíká wa ló máa nílò àtìlẹ́yìn wa láti ìgbà dégbà. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní ipá, àti ànfààní, gẹ́gẹ́ bí ojúṣe náà ṣe sọ láti fún àwọn ènìyàn ní ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹ́yìn tí kò ṣe é fowó rà, pàápàá jùlọ àwọn tí a ń tàpá sí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn.”
Wo ni kikun testimonial… -
DINA KAPARDIS MPhil Criminology, University Of Cambridge
“OBÌNRAN KAN LẸ́Ẹ̀KAN ṢOṢO jẹ́ ìdí tí àjọ tó bá n tọ́jú ọmọ ènìyàn ṣe yẹ kó wà. Dídáàbòbò Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn àti Ríró ènìyàn lágbára nípa pípèsè àtìlẹ́yìn àti ìtọ́ni tó tọ̀nà fún ni.”
-
NICOLA SMITH Àrẹ, FREEDOM DOLLS INITIATIVE
“Ó jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn obìnrin kọ̀ọ̀kan kí wọ́n mọ̀ wí pé ààbò wà fún àwọn ní ilé wọn. OWAAT mú òfin wá fún àwọn obìnrin ní ọ̀nà tí yóò fi ró wọn lágbára láti lè gba àkóso ilé ayé wọn. Kí wọn kó sì lè dojúkọ ìwà ipá. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti gbé ilé ayé láìsí ìwà ipá nínú, ṣíra tẹ̀ lórí ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù OWAAT. Arábìnrin ìgbésẹ̀ sí ayé tuntun ló ń gbé yìí.”
Wo ni kikun testimonial… -
ANASTASIA GEORGOULI Onímọ̀ Ẹ̀rọ Tó Ń Ṣiṣẹ́ Ara Rẹ̀ Ní JYA Engineering
“Mò ń ti ètò OWAAT lẹ́yìn nítorí pé mo gbàgbọ́ wí pé yóò ran àwọn obìnrin lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ara wọn, ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn tí wọ́n ní, àti wí pé wọn yóò lè gbé ìgbé ayé tó yẹ tí kò sì ní ariwo nínú. Wọn yóò sì tún fún wọn ní ọ̀nà láti bèrè fún àyè tó dára si nípasẹ̀ ìlànà tó rọrùn.”
-
CARLOS PARTASIDES Ó Ń Ṣiṣẹ́ Ní Ilé Iṣẹ́ Òfin Ti Achilles & Emile C. Emilianides LLC
“OWAAT ṣe pàtàkì gan ní Cyprus nítorí pé ìlépa rẹ̀ ni láti ró àwọn obìnrin tí a ti lò nílòkulò lágbára, ìyẹn nìkan kọ́ sì ni wọ́n ń lépa, wọ́n tún ń lépa láti ró gbogbo àwọn ènìyàn Cyprus náà lágbára láti lè mú àwùjọ wọn “Kó má Fàyè Gba Ìlokulò àwọn Obìnrin Rárá”. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé Ètò Òfin ìlú Cyprus máa ń ṣe atótónu púpọ̀, àti pẹ̀lú pé ó máa ń dá ohun dúró fún ìgbà pípẹ́, ní èrò tèmi, OWAAT yóò pèsè irinṣẹ́ fún àwọn obìnrin láti lè fi jà fún ẹ̀tọ́ wọn ní kíákíá fúnra wọn, tàbí kí o tọ́ wọn sọ́nà láti lépa ẹ̀tọ́ wọn.”
Wo ni kikun testimonial… -
CASSANDRA KOUPARI Kassandra Koupari & Ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀ / Agbẹjọ́rò. Ó jẹ́ alátìlẹ́yìn tó ń ṣiṣẹ́ gan láti máa dúró fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin, pàápàá jùlọ àwọn tí wọ́n ti farapa nípasẹ̀ ìlòkulò irúfẹ́ èyíkèyí
“O kò ní láti gbé ẹ̀sùn irọ́ sílẹ̀ kí o tó lè ní ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. Ètò OWAAT wá láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni, kí wọ́n sì máa rán ẹ létí, àwọn ohun tí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn rẹ jẹ́, kí o ba lè máa yan ẹ̀yàn rẹ bó ti yẹ. Mo gbàgbọ́ wí pé a ní láti ṣàtúnṣe òfin kí àwọn eniyan lè ráyè sí ìlànà òfin, kí ó sì rọrùn si láti lò ó bí i FACEBOOK, kí o ba lè somọ, tàbí kí o kúrò lórí wẹẹbu rẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Inú wa dùn sí irú okun yìí láti lè mú ìdarí ọ̀tun bá OWAAT.”
-
KATERINA ANDREOU Ògbóntaàgì Lórí Ìdáàbòbò Ọmọdé – Atọ́nisọ́nà
“Bí a ṣe ń ró àwọn obinrin wọ̀nyí ní agbára yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàtúngbéyẹ̀wò ara wọn, bóyá àwọn náà jẹ́ ẹni tó ń fikún àwùjọ, kò sì ní jẹ́ ohun tí àwọn tó fìyà jẹ wọ́n sọ fún wọn pé wọ́n jẹ́ ni wọn yóò máa gbàgbọ́ lọ. Ìṣesí yìí ṣe pàtàkì gan tí Cyprus bá máa yípadà ní tòótọ́, kí àwọn obinrin wọ̀nyí sì gba ayé wọn padà.”
Wo ni kikun testimonial… -
ROSSELLA SALA LLM In European And Transnational Law / Aṣojú ONE Youth / Adarí Agbègbè UNICEF Ní Italy
“Ohun tí OWAAT dá lé ni ìgbàgbọ́ kan tó wọ́pọ̀ láàrin wa wí pé a gbọ́dọ̀ fún obinrin kọ̀ọ̀kan lánfààní lá ti tú ohun tó wà nínú wọn sílẹ̀ nípasẹ̀ kíkọ́ nípa ẹ̀tọ́ wọn àti bí a ṣe lè dáàbòbò bò wọ́n. Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan, pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí, jẹ́ ohun ọlá àti ìpèníjà fún mi: bí inú mi ṣe dùn wí pé mo wà lára àwọn ẹgbẹ́ tó ń mú ìyàtọ̀ bá ayé àwọn obinrin ní Cyprus láti ró wọn lágbára, bẹ́ẹ̀ náà ni mo tún ṣe mọ̀ wí pé ipasẹ̀ tó wà níwáju mi gùn gan, ó sì tún ṣòro ó gùn.”
Wo ni kikun testimonial… -
CHRISTINA DEMETRIADES Atọ́nisọ́nà & Agbani Ńimọ̀ràn
“Ètò iṣẹ́ OWAAT ti mú àyípadà ńlá bá ọ̀nà ìráyè sí ìdájọ́ òtítọ́ ní Cyprus, bẹ́ẹ̀ ló sì ní ipa láti mú òpin dé bá ìlòkulò àwọn obìnrin tí wọ́n dákẹ́ nílé. Nípa ṣíṣàgbékalẹ̀ ayé tó dọ́gba, tó sì rọrùn sí ìdájọ́ àti lílo Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyan, yóò ṣàgbékalẹ̀ àpẹẹrẹ ńlá láti tẹ̀lé ní àwọn ibò mìíràn nínú ètò òfin fún àwọn ará ìlú. Nípa báyìí, tí a bá ń mú kí ìdàgbàsókè dé bá ìdọ́gba láàrin ọkùnrin àti obìnrin láwùjọ àti nínú àṣà wa, níkẹyìn èrò OWAAT di àmúṣẹ. Yóò jẹ́ ìtají fún àyípadà ọ̀tun láwùjọ. Pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ yìí jẹ́ ohun ìwúrí fún mi gan!”
-
MIDIEIA MASOUKATIDOU Òngbufọ̀ OWAAT Ní Greek/Russian
“Fífi owó ipá ati ìwa jàgidijàgan kolu awon obìnriñ jé oun ìtìjùú ti ó burú jùló ninu awón òfīn tí a sē fun ìdáàbòbò awon omo ènìyan. Ìwà kíwà yìí wà ni ibi gbogbo; bí a tí nri láàrin awon olówo beè ni ó wà láarin awon aláìni, kò sì bìkità fun ibi tabì ìlùu tí ènìyàn ti wá. Ninu gbogbo eléyi, l’aì tan arawaję, a ò le rí ìló siwaju, àlaáfià ati ìfòkàn b’alè. Laì si tàbi tàbií, nse ni ìwà búburú yìi sí awon omo obìnrin ilè Kipru npeléke si ni. Èyi já sí wipé a gbodò wàá ònà àbayo lati gb’oju ko ìwà kíwà yìí: ó pò n’ípá ati ní agbára.”
Wo ni kikun testimonial… -
BLANCA CASIELLES Ó Jẹ́ Onítọ̀ọ́jú Ilé Aláàdáni Fún Ilé Àti Ìtọ́jú Òdòdó / Akọ́ni Ní Èdè Spanish
“OWAAT jẹ́ àgbáj ọpọ̀ ọwọ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọ eniyan fún àwọn obìnrin tó ń jìyà lọ́wọ́ ìwà ipá nílé. Patricia jẹ́ ká rí àwọn ìṣòro tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin dá wà pẹ̀lú ẹ̀rù nílé wọn. Ó sì fún wa ní ànfààní láti ṣiṣẹ́ papọ̀, àti ọkùnrin àti obìnrin láti jà fún ohun kan náà. Ó jẹ́ ànfààní ńlá fún mi láti jẹ́ Olùdásílẹ̀ OWAAT – Alájọṣiṣẹ́pọ̀ Agbègbè, àti pé mo fi owó idẹ méjì mi sílẹ̀.”
-
ALISA KHANDYUK Ojogbon Ti Russian Ati Yukirenia Ede / Litireso Onitumo
“Ní àkọ́kọ́, mo jẹ́ ìyá fún ọmọ méjì. Nígbàkígbà tí mo bá ń gbàdúrà sí Ọlọrun, àdúrà mi ni pé kó máa dáàbòbò wọ́n, kí wọ́n sì ní ayé tí ó dára. Tó bá yá àwọn ọmọbìnrin mi yóò dàgbà, wọn yóò sì di obìnrin, mi ò ti ẹ̀ fẹ́ rò ó nínú ọkàn mi wí pé wọn yóò ní ìrírí ìlòkulò ní ọ̀nàkọnà rárá.”
Wo ni kikun testimonial… -
SOPHIA PAPASTAVROU ABD / Eka Àdíréşì Idajo Eko (SJE)
“OWAAT máa ń ró àwọn obìnrin àti ọmọbìnrin lágbára nípa pé wọn yóò ri dájú pé wọ́n fún wọn ní àtìlẹ́yìn tí wọ́n nílò, wọn yóò lè fi di ẹni tó ń kópa dáadáa nípa “ìṣàtúnkọ́” agbègbè wọn, kó lè wà láìsí ìlòkulò, ìfi ìyàtọ̀ sí àti ìdẹ́rùbà níkẹyìn. Wọn a lè bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin. Bí OWAAT ṣe máa ń ṣiṣẹ́ máa ń fàyè gbà wọ́n láti bá oríṣiríṣi àìní àwọn obìnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún pàdé. Wọn yóò sì tún ri pé àwọn tẹnumọ́ ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọbinrin, èyí yóò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àyípadà tí yóò pẹ́ títí wá.”
Wo ni kikun testimonial… -
JULIA-GEORGIA TOPINTZI Ọ̀jọ̀gbọ́n Èdè Àti Lítíréṣọ̀ German / Òngbufọ̀ Àti Alákoso Ẹgbẹ́ Òngbufọ̀ OWAAT / Akẹ́kọ̀ọ́ Ìmọ̀ Òfin Ní Ilé Ìwé Gíga Tí Nicosia
“Mo pinnu láti ṣiṣẹ́ fún OWAAT nítorí pé ìmọ̀ràn àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń fún àwọn ènìyàn ní àjọ yìí lè yí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin padà, pàápàá jùlọ bí a ṣe ń sọ lọ́wọ́ yìí, àwọn kan ṣì ń jìyà ìlòkulò lọ́wọ́, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ ìdáàbòbò. Pé kí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ojú wọn ń rí kì í ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe. OWAAT ń jà fún gbogbo àwọn obìnrin wọ̀nyí tí wọ́n nílò àtìlẹ́yìn láti lè dá dúró lórí ẹsẹ̀ wọn méjéèjì, kí wọ́n sì bèrè fún ọjọ́ ọ̀la tó dára fún ara wọn àti àwọn ọmọ wọn.”
-
OLUWATODIMU BANKOLE ti a tun mo si “TODI” O je akẹ́kọ̀ọ́ ni eka nípa ìmọ̀ òfin ní UCLAN ní orílẹ̀-èdè Cyprus / Oun tun je aja fun eto omo eniyan fun àjọ Europe ati Amnesty International / Ongbufo Yoruba fun OWAAT
“Idi ti mo se darapo mo OWAAT nipe o je agbenuso Pataki fun eto awon obinrin. O si je ohun iyi nla fun mi lati sise fun ajo to lola, ti won si faraji si ilepa won. OWAAT maa n ko awon obinrin ati awon okunrin nipa idi ti won fi ni lati mo eto awon obinrin ki won si ja fun un. Iwai pa lori awon obinrin je ohun idaamu nla ni Orile-ede Cyprus, ti a si ni lati dojuko pelu gbogbo ipa ati agbara lawujo wa.”
Wo ni kikun testimonial… -
STEPHANIE WILLIAMS J.D. / Alága Àná Fún, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn Kárí-Ayé Ti ABA, SIL
“Mo gbé OWAAT ní Cyprus yọ lórí ètò Silent All These Years, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ohun mẹ́rìndínlógún tí a ní láti Ṣàtìlẹ́yìn fún ní ọdún 2016 nítorí pé OWAAT máa ń pèsè àyè fún àwọn obìnrin láti ráyè sí òfin àti àwọn ohun mìíràn tí wọ́n nílò láti lè dúró fúnra wọn nílé ẹjọ́. Mò ń gbé ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù Ẹ̀tọ́ Ọmọ Eniyan OWAAT kárí ayé bó ṣe ń pèsè irinṣẹ́ tó péye tí àwọn obìnrin, pàápàá jùlọ àwọn tí a ti lò nílòkulò lè ṣàmúlò láti fi ró wọn lágbára.”
-
PHOEBE COLES Jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ àṣekágbá nípa ìmọ̀ òfin ní UCLAN ní orílẹ̀-èdè Cyprus
Phoebe tún ọ̀rọ̀ Martin Luther King sọ gẹ́gẹ́ bí ìdí tó fi jọ̀wọ́ ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ OWAAT:
“Ibikíbi tí àìṣòdodo bá wà, ẹ̀rù ló jẹ́ fún òdodo níbikíbi.” Ó wá sọ pé: ” Ó jẹ́ ìlépa òun láti wà lára àwọn tó dojú ìjà kọ àìdọ́gba àti ìnilára gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́ro Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn Kárí-ayé. Mo sì ní ìtara gidi gan fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.” -
ANTONIA MICHAELS Jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìmọ̀ Òfin ní UCLAN, Ongbufo Greek fun OWAAT
“Nígbà mìíràn a kì í mọ̀ iyì Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn wa,” àti wí pé àwọn tí a ti lò ní ìlòkulò ló máa ń rán wa létí wí pé ẹ̀tọ́ wa jẹ́ ohun tí a ní láti máa jà fún nígbà gbogbo. OWAAT jẹ́ àjọ tó ní ọlá púpọ̀, tó ń sọ fún àwọn obìnrin nípa ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn wọn, ṣùgbọ́n ó tún máa ń ró wọn lágbára pẹ̀lú ìmọ̀ láti mọ̀ wí pé wọ́n ní láti gbàkóso ilé ayé wọn, wọn yóò sì rí ìwòsàn lẹ́yìn gbogbo ìjìyà tí wọ́n ti faradà. Ohun tí mo fẹ́ ṣe ni láti ran OWAAT lọ́wọ́ ní láti lè mú ìlépa rẹ̀ ṣẹ ní kíkún. Jíjọ̀wọ́ ara ẹni jẹ́ ohun ànfààní fún ẹni tó ń gba ìrànlọ́wọ́ àti ẹni tó ń fún ni pẹ̀lú.”
-
SARAH ALSABTI Òngbufọ̀ OWAAT ní English - Arabic
“Oje ohun iwuri at idunu fun mi, lati darapo mo egbe awon obirin ti won dagangia, ti won gbagbo ni ilosiwaju ati ito oju awon obirin. Won ja takun takun lati ri wipe ako fi iya je awon obirin. Won sin ri daju wipe ni ona meji ototo ni won fin gbeja awon ibirin ti a fi iyaje abi du ni owun eto won.ni ona kini,won ma se idani leko,ati ipolongo fun won lati mo eto won, ati ko bi won le ti koya fun ara won ati ki won ma fi iya je ara won. Ona keji ewe ni wipe, won gbe eto kale lati rii daju wipe obirin ti a ba da loro tabi fi iyaje Ri iwosan to peye ati abo to daju. Won a duro ti iru obirin be titi ti oro aye re yio ni’yanju ti gbogbo ikolo tabi eto re yio pada je ti re Lai sanwo fun agbejoro kankan. Mo lero wipe gege bi olutumo ati ogbufo fun ede larubawa wulo osi se anfani fun ilisiwaju egbe wa yi”
-
AYS LIDZHANOVA Attorney, PhD ti o je akeko gboye ti o ga julo ni imo agbejoro ni egbe OWAAT
“Mo gbe oriyin fun OWAAT fun ise taakun, taakun ti won se larin awon obirin ilu, latiri wipe won o fi eto won du won. won je ohun ati olugbeja awon ti ati fi iya je ati ti afe du ni eto won. Won nu omije kuro loju awon ti sokun, asi rii daaju wipe Ijoba anti gbogbo egbe ti o ye nse eto won si gbogbo eya eniyan, pappa julo obirin lomode ait lagba. O je idunu funmi lati darapo mo OWAAT paapajulo ni ti oludasile ti o yanranti anti awon aladari ti won fi ara jin lati ri daju wipe iditi a fi da OWAAT sile di mimuse.”
-
SPAVO Ẹgbẹ́ Tó Máa Ń Mójútó Dídènà Ìwà Ipá Nínú Ẹbí
“A ṣàtìlẹ́yìn fún OWAAT láti ró àwọn obìnrin lágbára àti láti gba ẹ̀tọ́ wọn padà.”
Wo ni kikun testimonial…